1. Wọ̀nyí ni ìrìnàjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ẹsẹẹsẹ, nígbà tí wọ́n tí ilẹ̀ Íjibítì jáde wá pẹ̀lú àwọn ogun wọn, nípa ọwọ́ Mósè àti Árónì.
2. Mósè sì kọ̀wé ìjáde lọ wọn ní ẹsẹẹsẹ gẹ́gẹ́ bí ìrìnàjò wọn, nípa àṣẹ Olúwa; Wọ̀nyí sì ni ìrìnàjò wọn gẹ́gẹ́ bí ìjáde lọ wọn.
3. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jáde kúrò láti Rámésesì ní ọjọ́ kẹ́ẹdógún osù kìn-ín-ní, ọjọ́ kan lẹ́yìn àjọ Ìrékọja. Wọ́n yan jáde pẹ̀lú ìgboyà níwájú gbogbo àwọn ará Éjíbítì.