Nọ́ḿbà 31:41-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Mósè fi ìdá náà fún Élíásárì, àlùfáà gẹ́gẹ́ bí ìdá ti Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mósè.

42. Ààbọ̀ tí ó jẹ́ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tí Mósè yà sọ́tọ̀ kúrò lára àwọn ọkùnrin tí ó ja ogun.

43. (Ààbọ̀ tí àwọn ará ìlú sì jẹ́ ẹgbàá méjìdínláàdọ́sàn-án ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ (337,500) àgùntàn,

44. pẹ̀lú ẹgbàá méjìdínlógún (36,000) màlúù

45. tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́ẹ̀dógún ó lé ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta. (30,500)

46. Àwọn ènìyàn sì jẹ́ ẹgbàá mẹ́jọ;) (16,000).

47. Lára ààbọ̀ ti àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Mósè yan ọ̀kan lára àádọ́ta (50) ènìyàn àti ẹranko gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un. Ó sì fi wọ́n fún àwọn ọmọ Léfì, tí ń ṣe olùtọ́jú àgọ́ Olúwa.

Nọ́ḿbà 31