1. “ ‘Ní ọjọ́ kìn-ín-ní, oṣù keje, kí ẹ ní àpéjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan. Ọjọ́ ìfúnpè ni ó jẹ́ fún yín.
2. Gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn sí Olúwa, ẹ pèsè ẹgbọ̀rọ̀ akọ màlúù kan, àgbò kan àti akọ ọ̀dọ́ àgùntàn ọlọ́dún kan aláìlábùkù, kí ẹ fi ẹbọ sísun.
3. Pẹ̀lú ẹbọ ohun jíjẹ wọn, ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá òṣùwọ̀n fún akọ màlúù kan, àti ìdáméjì nínú mẹ́wàá, òṣùwọ̀n fún àgbò kan,