Nọ́ḿbà 28:14-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Kí ẹbọ ohun mímu wọn jẹ́ ààbọ̀ òṣùwọ̀n hínì ti ọtí wáìnì, fún akọ màlúù kan, àti ìdámẹ́wàá òṣùwọ̀n hínì fún àgbò kan àti ìdámẹ́rin òṣùwọ̀n hínì fún ọ̀dọ́ àgùntàn kan. Èyí ni ẹbọ sísun tí wọn ó máa rú ní oṣù kọ̀ọ̀kan nínú ọdún.

15. Yàtọ̀ sí ẹbọ sísun pẹ̀lú ẹbọ ohun mímu, ẹ gbọdọ̀ fi akọ ewúrẹ̀ kọ̀ọ̀kan fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀.

16. “ ‘Ní ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ní-ní ni ìrékọjá Olúwa gbọdọ̀ wáyé.

17. Ní ọjọ́ kẹẹ́dógún oṣù yìí ẹ gbọdọ̀ ṣiṣẹ́ àjọ̀dún fún ọjọ́ méje kí ó jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.

18. Ní ọjọ́ kìn-ní-ní ni kí ẹ ṣe ìpàdé àjọ mímọ́ kí ẹ wá kí ẹ sì má ṣe iṣẹ́ kankan.

19. Ẹ rú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, ẹ rú u pẹ̀lú ọ̀dọ́ màlúù méjì akọ, ẹbọ sísun pẹ̀lú iná àgbò kan àti ọ̀dọ́ àgùntàn méje ọlọ́dún kọ̀ọ̀kan kí wọn kí ó jẹ́ aláìlábùkù.

20. Pẹ̀lú akọ màlúù kọ̀ọ̀kan ni kí ẹ pèsè ẹbọ ohun mímu pẹ̀lú ìdámẹ́ta nínú mẹ́wàá ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò; pẹ̀lú àgbò, ìdá méjì nínú mẹ́wàá;

21. pẹ̀lú ọ̀dọ̀ àgùntàn kọ̀ọ̀kan ida kan nínú mẹ́wà.

22. Pẹ̀lú òbúkọ kan fún ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ láti ṣètùtù fún un yín.

23. Ṣe eléyí ní àfikún sí ẹbọ sísun àràárọ̀.

24. Báyìí ní kí ẹ ṣe se oúnjẹ fún ẹbọ tí a fi iná ṣe ní ojojúmọ́ fún ọjọ́ méje gẹ́gẹ́ bí olóòrùn dídùn sí Olúwa; ó gbọdọ̀ jẹ́ èyí tí a fi iná ṣe ní àfikún ẹbọ ohun jíjẹ àti ohun mímu.

25. Ní ọjọ́ kéje kí ẹ̀yin kí ó ní ìpéjọ mímọ́, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe isẹ́ kankan.

26. “ ‘Ní ọjọ́ àkọ́so pẹ̀lú, nígbà tí ẹ̀yin bá mú ẹbọ ohun jíjẹ tuntun wá fún Olúwa lẹ́yìn àsìkò Àjọ̀dún, kí ẹ̀yin kí ó ní àpéjọ mímọ́, ẹ̀yin kò gbọdọ̀ se iṣẹ́ kankan.

Nọ́ḿbà 28