Nọ́ḿbà 21:8-12 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Olúwa sọ fún Mósè pé, “Rọ ejò, a ó sì gbé e kọ́ sókè lórí igi, ẹni tí ejò bá ti gé jẹ lè wò ó yóò sì yè.”

9. Nígbà náà ni Mósè sì rọ ejò onírin ó sì gbé e kọ́ sórí igi, Bí ejò bá sì bu ẹnikẹ́ni jẹ bí ó bá ti wò ó yóò sì yè.

10. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀ṣíwájú wọ́n sì péjọ sí Óbótì.

11. Wọ́n gbéra ní Óbótì wọ́n sì pa ibùdó sí Iye-àbárímù, ní ihà tí ó kọjú sí Móábù ní ìdojúkọ ìlà oòrùn.

12. Láti ibẹ̀ ni wọ́n ti gbéra wọ́n sì pa ibùdó ní àfonífojì Sérédì.

Nọ́ḿbà 21