Nọ́ḿbà 19:6-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Àlùfáà yóò mú igi òpépé, hísópù àti òwú òdòdó yóò sì jù wọ́n sí àárin ọ̀dọ́ abo màlúù tí a ń sun.

7. Lẹ́yìn náà, Àlùfáà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀, kí ó sì wẹ ara rẹ̀ pẹ̀lú omi lẹ̀yìn náà ó lè wá sínú àgọ́. Ṣùgbọ́n yóò jẹ́ aláìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

8. Ẹni tí ó sun ún náà gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀ pèlú omi, òun náà yóò jẹ́ aláìmọ́ títi di ìrọ̀lẹ́.

Nọ́ḿbà 19