Nọ́ḿbà 13:20-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

20. Báwo ni ilẹ̀ náà ti rí? Ṣé ilẹ̀ ọlọ́ràá ni tàbí aṣálẹ̀? Ṣé igi wà níbẹ̀ àbí kò sí? E sa ipá yín láti rí i pé ẹ mú díẹ̀ nínú èso ilẹ̀ náà wá.” (Ìgbà náà sì jẹ́ àkókò àkọ́pọ́n èṣo àjàrà gíréépù.)

21. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n gòkè lọ láti yẹ ilẹ̀ náà wò, wọ́n lọ láti Aginjù Ṣínì títí dé Réhóbù lọ́nà Lébò Hámátì.

22. Wọ́n gba Gúsù lọ sí Hébírónì níbi tí Áhímánì, Ṣésáì àti Tálímà tí í se irú ọmọ Ánákì ń gbé. (A ti kọ́ Hébúrónì ní ọdun méje ṣáájú Ṣánì ní Éjíbítì.)

23. Nígbà tí wọ́n dé àfonífojì Éṣíkólù, wọ́n gé ẹ̀ka kan tó ní ìdì èṣo àjàrà gíréèpù kan. Àwọn méjì sì fi ọ̀pá kan gbé e; wọ́n tún mú èṣo pomegíránétì àti èṣo ọ̀pọ̀tọ́ pẹ̀lú.

24. Wọ́n sì sọ ibẹ̀ ní àfonífojì Ésíkólù nítorí ìdí èso gíréépù tí wọ́n gé níbẹ̀.

25. Wọ́n padà sílé lẹ́yìn ogójì ọjọ́ tí wọ́n ti lọ yẹ ilẹ̀ náà wò.

26. Wọ́n padà wá bá Mósè àti Árónì àti gbogbo àwọn ọmọ Ísiréli ní ijù Kádésí Páránì. Wọ́n mú ìròyìn wá fún wọn àti fún gbogbo ìjọ ènìyàn, wọ́n fi èso ilẹ̀ náà hàn wọ́n.

27. Wọ́n sì fún Mósè ní ìròyìn báyìí: “A lọ sí ilẹ̀ ibi tí o rán wa, lóótọ́ ló sì ń sàn fún wàrà àti fún oyin! Èṣo ibẹ̀ nìyìí.

28. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn tó ń gbé níbẹ̀ lágbára, àwọn ìlú náà jẹ́ ìlú olódi bẹ́ẹ̀ ni ó sì tóbi púpọ̀. A tilẹ̀ rí àwọn irú ọmọ Ánákì níbẹ̀.

Nọ́ḿbà 13