11. Ní ogúnjọ́ oṣù kejì, ní ọdún kejì ni ìkùukù kúrò lórí tabánákù Ẹ̀rí.
12. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì gbéra kúrò ní ihà Sínáì wọ́n sì rin ìrìnàjò wọn káàkiri títí tí ìkùukù fi dúró sí ihà Páránì.
13. Wọ́n gbéra nígbà àkọ́kọ́ yìí nípa àṣẹ Olúwa láti ẹnu Mósè.
14. Àwọn ìpín ti ibùdó Júdà ló kọ́kọ́ gbéra tẹ̀lé wọn lábẹ́ ogun wọn Náṣónì ọmọ Ámínádábù ni ọ̀gágun wọn.
15. Nẹ̀taníẹ́lì ọmọ Ṣúárì ni ọ̀gágun ti ẹ̀yà Ísákárì;
16. Élíábù ọmọ Hélónì ni ọ̀gágun ni ìpín ti ẹ̀yà Ṣébúlúnì.