Nehemáyà 3:11-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

11. Málíkíjà ọmọ Hárímù àti Háṣúbù ọmọ Páhátì—Móábù tún ẹ̀gbẹ́ kejì ṣe àti Ilé-ìṣọ́ Ìléru.

12. Ṣálúmù ọmọ Hálọ́ésì, alákóṣo ìdajì agbégbé Jérúsálẹ́mù tún ti ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ mọ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀

13. Ibodè Àfonífojì ni Hánúnì àti àwọn ará Ṣánóà tún mọ. Wọ́n tún-un kọ́ wọ́n ri àwọn ìlẹ̀kùn àti àwọn ide rẹ̀ sí ààyè rẹ̀. Wọ́n sì tún tún ẹgbẹ̀rún-ún kan ìgbọ̀nwọ odi mọ títí dé ẹnu ibodè ààtàn.

Nehemáyà 3