Nehemáyà 12:39-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

39. Kọjá ẹnu ibodè Éúfúrẹ́mù ibodè Jéṣánà, ẹnu ibodè ẹja, ilé ìṣọ́ Hánánélì àti ilé ìṣọ́ ọgọ́rùn—ún, títí dé ẹnu ibodè àgùntàn. Wọ́n sì dúró ní ibodè ìṣọ́.

40. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin méjèèjì tí wọ́n dúpẹ́ wà ní ààyè nínú ilé Ọlọ́run, èmi náà sì dúró ní ààyè mi pẹ̀lú ìdajì àwọn ìjòyè,

41. Àti àwọn àlùfáà—Élíákímù, Máṣéyà, Míníámínì, Míkáyà, Éliánáyì, Ṣaráyà àti Hananáyà pẹ̀lú àwọn ìpèe (kàkàkí) wọn.

42. Àti pẹ̀lú Maáṣéyà, Ṣémáyà, Éṣérì. Àwọn ẹgbẹ́ akọrin ní abẹ́ ìṣàkóso Jéṣíráyà.

Nehemáyà 12