8. Nígbà tí ìjọ ènìyàn rí í ẹnu sì yà wọ́n, wọ́n yin Ọlọ́run lógo, ti ó fi irú agbára báyìí fún ènìyàn.
9. Bí Jésù sì ti ń rékọjá láti ibẹ̀ lọ, o rí ọkùnrun kan ti à ń pè ní Mátíù, ó jókòó ní ibùdó àwọn agbowó-òde, ó sì wí fún un pé, “Máa tọ̀ mí lẹ́yìn,” Mátíù sì dìde, ó ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.
10. Ó sì ṣe, bí Jésù tí jókòó ti ó ń jẹun nínú ilé Mátíù, sì kíyèsí i, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó-òde àti “ẹlẹ́sẹ̀” wá, wọ́n sì bá a jẹun pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.
11. Nígbà tí àwọn Farisí sì rí i, wọ́n wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “ ‘Èé ṣe’ tí Olùkọ́ yín fi ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́sẹ̀ jẹun pọ̀?”
12. Ṣùgbọ́n nígbà tí Jésù gbọ́ èyí, ó wí fún wọn pé, “Àwọn tí ara wọ́n le kò wá oníṣègùn bí kò ṣe àwọn tí ara wọn kò dá.