16. “Kò sí ẹni tí í fi ìrépé aṣọ tutun lẹ ògbólògbó ẹ̀wù; nítorí èyí tí a fi lẹ̀ ẹ́ yóò ya ní ojú lílẹ̀, aṣọ náà yóò sì ya púpọ̀ sì i ju ti ìṣáájú lọ.
17. Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ẹni tí fi ọtí titun sínú ògbólògbó ìgò-awọ; bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ìgò-àwọ yóò bẹ́, ọtí á sì tú jáde, ìgò-àwọ á sì ṣègbé. Ṣùgbọ́n ọtí titun ni wọn í fi sínú ìgò-àwọ tuntun àwọn méjèèjì a ṣì ṣe dédé.”
18. Bí ó ti ń sọ nǹkan wọ̀nyí fún wọn, kíyèsí i, ìjòyè kan tọ̀ ọ́ wá, ó sì wólẹ̀ níwájú rẹ̀ wí pé, “Ọmọbìnrin mi kú nísinsìn yìí, ṣùgbọ́n wá fi ọwọ́ rẹ̀ lé e, òun yóò sì yè.”
19. Jésù dìde ó sì bá a lọ àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀.