1. “Ẹ kíyè ṣára kí ẹ má ṣe iṣẹ́ rere yín níwájú àwọn ènìyàn nítorí kí a le rí yín, Bí ẹ bá ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin kò lérè kankan lọ́dọ̀ Baba yín ní ọ̀run.
2. “Nítorí náà, nígbà ti ẹ ń bá ti fún aláìní, ẹ má ṣe fi kàkàkí kéde rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwọn àgàbàgebè ti í ṣe ní sínágọ́gù àti ní ìta gbangba; kí àwọn ènìyàn le yìn wọ́n. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, wọ́n ti gba èrè tí wọn ní kíkún.
3. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ńfi fún aláìní, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ òsì rẹ mọ ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ ń ṣe,
4. kí ìfúnni rẹ má ṣe jẹ́ mímọ̀. Nígbà náà ni Baba rẹ̀, tí ó sì mọ ohun tí ìkọ̀kọ̀ gbogbo, yóò san án fún ọ.