Mátíù 4:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Nígbà náà ni Ẹ̀mí Mímọ́ darí Jésù sí ihà láti dán an wò láti ọwọ́ èsù.

2. Lẹ́yìn tí Òun ti gbààwẹ̀ ní ogójì ọ̀sán àti ogójì òru, ebi sì ń pa á.

3. Nígbà náà ni olùdánwò tọ̀ ọ́ wá, ó wí pé, “Bí ìwọ bá ṣe Ọmọ Ọlọ́run, pàṣẹ kí àwọn òkúta wọ̀nyí di àkàrà.”

Mátíù 4