Mátíù 2:14-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

14. Nígbà náà ni ó sì dìde, ó mú ọmọ-ọwọ́ náà àti ìyá rẹ̀ ní òru, ó sì lọ sí Éjíbítì,

15. ó sì wà níbẹ̀ títítí Hẹ́rọ́dù fi kú. Èyí jẹ́ ìmúṣẹ àṣọtẹ́lẹ̀ ohun tí Olúwa sọ láti ẹnu wòlíì pé: “Mo pe ọmọ mi jáde láti Éjíbítì wá.”

16. Nígbà tí Hẹ́rọ̀dù rí í pé àwọn amòye náà ti tan òun jẹ, ó bínú gidigidi, ó sì pàṣẹ kí a pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí ó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní ẹkùn rẹ̀ láti àwọn ọmọ ọdún méjì sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bi àkókò tí ó ti fi ẹ̀sọ̀ ẹ̀sọ̀ béèrè lọ́wọ́ àwọn amòye náà.

Mátíù 2