Mátíù 19:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Lẹ́yìn tí Jésù ti parí ọ̀rọ̀ yìí, ó kúrò ní Gálílì. Ó sì yípo padà sí Jùdíà, ó gba ìhà kejì odò Jọ́dánì.

2. Ọ̀pọ̀ ènìyàn sì ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, ó sì mú wọn láradá níbẹ̀.

3. Àwọn Farisí wá sọ́dọ̀ rẹ̀ láti dán an wò. Wọ́n bi í pé, “Ǹjẹ́ ó tọ̀nà fún ọkùnrin láti kọ ìyàwó rẹ̀ sílẹ̀ nítorí ohunkóhun?”

4. Ó dáhùn pé, “A ti rí i kà pé ‘ní ìpilẹ̀sẹ, Ọlọ́run dá wọn ni ọkùnrin àti obìnrin.’

Mátíù 19