5. Nígbà tí wọ́n dé apá kejì adágún, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sàkíyèsí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà kankan lọ́wọ́.
6. Jésù sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyè sára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisí àti àwọn Sadusí.”
7. Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárin ara wọn nítorí pé wọ́n ti gbàgbé láti mú àkàrà lọ́wọ́.
8. Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èé ṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́?
9. Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsìn yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹẹ́dọ́gbọ́n (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìsù búrẹ́dì márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kó jọ bí àjẹkù?