Mátíù 13:54-56 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

54. Ó wá sí ìlú òun tìkára rẹ̀, níbẹ̀ ni ó ti ń kọ́ àwọn ènìyàn nínú Ṣínágọ́gù, ẹnu sì yà wọ́n. Wọ́n béèrè pé, “Níbo ni ọkùnrin yìí ti mú ọgbọ́n yìí àti iṣẹ́ ìyanu wọ̀nyí wá?

55. Kì í há ṣe ọmọ gbẹ́nàgbẹ́nà ni èyí bí? Ìyá rẹ̀ há kọ́ ni à ń pè ní Màríà bí? Arákùnrin rẹ̀ ha kọ́ ni Jémísì, Jósẹ́fù, Símonì àti Júdásì bí?

56. Àwọn arábìnrin rẹ̀ gbogbo ha kọ́ ni ó ń bá wa gbé níhìn-ín yìí, nígbà náà níbo ni ọkùnrin yìí ti rí àwọn nǹkan wọ̀nyí?”

Mátíù 13