Málákì 1:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ọ̀rọ̀ ìjìnlẹ̀: ọ̀rọ̀ Olúwa sí Ísírẹ́lì láti ẹnu Málákì.

2. “Èmí ti fẹ́ ẹ yín,” ni Olúwa wí.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni ìwọ ṣe fẹ́ wa?’“Ísọ̀ kì í ha ṣe arákùnrin Jákọ́bù bí?” ni Olúwa wí. “Ṣíbẹ̀ èmi fẹ́ràn Jákọ́bù,

3. ṣùgbọ́n Ísọ̀ ni èmi kórìíra, mo ti sọ àwọn òkè-ńlá rẹ̀ di aṣálẹ̀, mo sì fi ìní rẹ̀ fún àwọn akáta ihà.”

4. Édómù lè wí pé, “Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a run wá, àwa yóò padà wá, a ó sì tún ibùgbé náà kọ́.”Ṣùgbọ́n èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ ogun wí pé: “Àwọ́n lè kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò wó palẹ̀. Wọn yóò sì pè wọ́n ní Ilẹ̀ Búburú, àwọn ènìyàn tí wọ́n máa ń wà ní ìbínú Olúwa.

5. Ẹ̀yin yóò sì fi ojú yín rí i, ẹ̀yin yóò sì wí pé, ‘Títóbi ni Olúwa, títóbi rẹ̀ tayọ kọjá agbègbè Ísírẹ́lì.’

6. “Ọmọ a máa bu ọ̀wọ̀ fún baba rẹ̀, ọmọ-ọ̀dọ̀ a sì máa bọlá fún ọ̀gá rẹ̀. Bí èmí bá jẹ́ baba ọ̀wọ̀ tí ó tọ́ sí mi dà? Bí èmi bá sì jẹ́ ọ̀gá ọlá, tí ó tọ́ sí mi dà?” ni Olúwa àwọn ọmọ ogun wí. “Ẹ̀yin ni, ẹ̀yin àlùfáà, ni ẹ ń gan orúkọ ọ̀ mi.“Ṣùgbọ́n ẹ̀yín béèrè pé, ‘Báwo ni àwa ṣe gan orúkọ ọ̀ rẹ?’

Málákì 1