Máàkù 9:12-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

12. Ó sì dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni Èlíjà yóò kọ́kọ́ dé yóò sì mú nǹkan gbogbo padà bọ̀ sípò. Àní gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé rẹ nípa ti Ọmọ-Ènìyàn pé kò le ṣàìmá jìyà ohun púpọ̀ àti pé a ó sì kọ̀ ọ́ sílẹ̀.

13. Ṣùgbọ́n mo wí fún yín pé, Èlíjà ti wa ná, wọ́n sì ti ṣe ohunkóhun tí ó wù wọ́n sí i, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀.”

14. Nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ pátápátá sí ẹ̀ṣẹ̀ òkè náà, wọ́n bá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí wọ́n yí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́sàn-án ìyókù ká. Àwọn olùkọ́-òfin díẹ̀ sì ń bá wọn jiyàn.

15. Bí Jésù ti ń súnmọ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn wọ̀nyí ni wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí í wò ó pẹ̀lú ìbẹ̀rù, nígbà náà ni wọ́n sáré lọ kí i.

16. Jésù béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ló fa àríyàn-jiyàn?”

17. Ọkùnrin kan láàrin ọ̀pọ̀ ènìyàn dáhùn pé, “Olùkọ́, èmi ni mo mú ọmọ yìí wá fún ọ láti wò ó sàn. Kò lè sọ̀rọ̀ rárá, nítorí tí ó ní ẹ̀mí àìmọ́.

18. Àti pé, nígbàkúùgbà tí ó bá mú un, á gbé e sánlẹ̀, a sì máa hó itọ́ lẹ́nu, a sì máa lọ́ ẹyín rẹ̀. Òun pàápàá a wá le gbàgìdì. Mo sì bẹ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ kí wọn lé ẹ̀mí àìmọ́ náà jáde, ṣùgbọ́n wọ́n kò lè ṣe é.”

Máàkù 9