Máàkù 7:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

1. Ní ọjọ́ kan, àwọn Farisí olùkọ́ àti àwọn òfin tí ó wá láti Jerúsálémù péjọ sí ọ̀dọ̀ rẹ̀,

2. Wọ́n sì ṣe àkíyèsí wí pé díẹ̀ nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jésù ń fi ọwọ́ àìmọ́ jẹun, èyí yìí ni wẹ ọwọ́.

3. (Àwọn Farisí, àti gbogbo àwọn Júù, bí wọ́n kò bá wẹ ọwọ́ wọn gidigidi, wọn kií jẹun nítorí wọ́n ti pa òfin àtọwọdọ́wọ́ àwọn àgbà mọ́.

Máàkù 7