Máàkù 11:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. Nígbà náà, púpọ̀ nínú ọ̀pọ̀ ènìyàn tẹ́ àṣọ wọn sójú-ọ̀nà níwájú u rẹ̀. Àwọn mìíràn ju ewéko ìgbẹ́ sílẹ̀.

9. Jésù wà láàrin ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn níwájú, lẹ́yìn, gbogbo wọn sì ń kígbe wí pé,“Hòsánà!”“Olùbùkún ni ẹni náà tí ó ń bọ̀ wà ní orúkọ Olúwa!”

10. “Olubùkún ni fún ìjọba tí ń bọ̀ wá, ìjọba Dáfídì, baba wa!”“Hòsánà lókè ọ̀run!”

11. Jésù wọ Jerúsálémù ó sì lọ sí inú tẹ́ḿpílì. Ó wo ohun gbogbo yíká fínnífínní. Ó sì kúrò níbẹ̀, nítorí pé ilẹ̀ ti sú. Ó padà lọ sí Bẹ́tanì pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá.

Máàkù 11