Máàkù 10:35-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

35. Lẹ́yìn èyí, Jákọ́bù àti Jòhánù, àwọn ọmọ Sébédè wá sọ́dọ̀ Jésù. Wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́, wọ́n wí pé, “Olùkọ́, inú wa yóò dùn bí ìwọ bá lè ṣe ojú rere ohunkóhun tí a bá béèrè fún wa.”

36. Jésù béèrè pé, “Kí ni Ẹ̀yin ń fẹ́ kí èmi ó ṣe fún un yín?”

37. Wọ́n bẹ̀bẹ̀ pé, “Jẹ́ kí ọ̀kan nínú wa jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ẹnikejì ní ọwọ́ òsì nínú ògo rẹ!”

Máàkù 10