Lúùkù 9:43-46 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

43. Ẹnu sì ya gbogbo wọn sí iṣẹ́ ọláńlá Ọlọ́run, ṣùgbọ́n nígbà tí hà sì ń ṣe gbogbo wọn sí ohun gbogbo tí Jésù ṣe, ó wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé,

44. “Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wọ̀ yín léti: nítorí a ó fi ọmọ-ènìyàn lé àwọn ènìyàn lọ́wọ́.”

45. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà kò yé wọn, ó sì ṣú wọn lójú, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sì mọ̀ ọ́n: ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti bèèrè ìdí ọ̀rọ̀ náà.

46. Iyàn kan sì dìde láàrin wọn, ní ti ẹni tí yóò ṣe olórí nínú wọn.

Lúùkù 9