18. Ó sì ṣe, nígbà tí ó ku òun nìkan ó gbàdúrà, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì wà lọ́dọ̀ rẹ̀: ó sì bi wọ́n pé, “Ta ni àwọn ènìyàn ń fi èmi pè?”
19. Wọ́n sì dáhùn wí pé, “Jòhánù Onítẹ̀bọmi; ṣùgbọ́n ẹlòmíràn ní Èlíjà ni; àti àwọn ẹlòmíràn wí pé, ọ̀kan nínú àwọn wòlíì àtijọ́ ni ó jíǹde.”
20. Ó sì bi wọ́n pé, “Ṣùgbọ́n tani ẹ̀yin ń fi èmi pè?”Pétérù sì dáhùn, wí pe, “Kírísítì ti Ọlọ́run.”
21. Ó sì kìlọ̀ fún wọn, ó sì pàṣẹ fún wọn, pé, kí wọn má ṣe sọ èyí fún ẹnìkan.
22. Ó sì wí pé, “Ọmọ ènìyàn yóò jìyà ohun púpọ̀, a ó sì kọ̀ ọ́ láti ọ̀dọ̀ àwọn alàgbà àti láti ọ̀dọ̀ àwọn akọ̀wé, a ó sì pa á, ní ijọ́ kẹta a ó sì jí i dìde.”
23. Ó sì wí fún gbogbo wọn pé, “Bí ẹnìkan bá ń fẹ́ láti má a tọ̀ mí lẹ́yìn, kí ó sẹ́ ara rẹ̀, kí ó sì gbé àgbélébùú rẹ̀ ní ọjọ́ gbogbo, kí ó sì máa tọ̀ mí lẹ́yìn.
24. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba ọkàn rẹ̀ là, yóò sọ ọ́ nù: ṣùgbọ́n ẹnikẹ́ni tí ó bá sọ ọkàn rẹ̀ nù nítorí mi, òun náà ni yóò sì gbà á là
25. Nítorí pé èrè kínni fún ènìyàn, bí ó jèrè gbogbo ayé, tí ó sì sọ ara rẹ̀ nù tàbí kí ó ṣòfò.
26. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá tijú mi, àti ọ̀rọ̀ mi, òun ni ọmọ ènìyàn yóò tijú rẹ̀ nígbà tí ó bá dé inú ògo tirẹ̀, àti ti baba rẹ̀, àti ti àwọn ańgẹ́lì mímọ́.
27. Ṣùgbọ́n èmi wí fún yín nítòótọ́, ẹlòmíràn dúró níhìnín yìí, tí kì yóò rí ikú, títí wọn ó fi rí ìjọba Ọlọ́run.”
28. Ó sì ṣe bí ìwọ̀n ijọ́ mẹ́jọ lẹ́yìn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó mú Pétérù àti Jòhánù àti Jákọ́bù, ó gun orí òkè lọ láti lọ gbàdúrà.
29. Bí ó sì ti ń gbàdúrà, àwọ̀ ojú rẹ̀ yípadà, aṣọ rẹ̀ sì funfun gbò,
30. Sì kíyèsí i, àwọn ọkùnrin méjì, Mósè àti Èlíjà, wọ́n ń bá a sọ̀rọ̀:
31. Tí wọ́n fi ara hàn nínú ògo, wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ ikú rẹ̀, tí òun yóò ṣe parí ní Jerúsálémù.
32. Ṣùgbọ́n ojú Pétérù àti ti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wúwo fún oorun. Nígbà tí wọ́n sì tají, wọ́n rí ògo rẹ̀, àti ti àwọn ọkùnrin méjèèjì tí ó bá a dúró.
33. Ó sì ṣe, nígbà tí wọ́n lọ kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, Pétérù wí fún Jésù pé, “Olùkọ́, ó dára fún wa kí a máa gbé ìhín yìí: jẹ́ kí àwa pa àgọ́ mẹ́ta; ọ̀kan fún ìwọ, àti ọ̀kan fún Mósè, àti ọ̀kan fún Èlíjà.” (Kò mọ èyí tí òun ń wí.)
34. Bí ó ti ń sọ báyìí, ìkùukù kan wá, ó ṣíji bò wọ́n: ẹ̀rù sì bà wọ́n nígbà tí wọ́n ń wọ inú ìkùukù lọ.
35. Ohùn kan sì ti inú ìkùukùu wá wí pé, “Èyí yìí ni àyànfẹ́ ọmọ mi: ẹ máa gbọ́ tirẹ̀.”
36. Nígbà tí ohùn náà sì dákẹ́, Jésù nìkan ṣoṣo ni a rí. Wọ́n sì pa á mọ́, wọn kò sì sọ ohunkóhun tí wọ́n rí fún ẹnikẹ́ni ní ọjọ́ wọ̀nyí.
37. Ó sì ṣe, ní ijọ́ kejì, nígbà tí wọ́n sọ̀kalẹ̀ wá láti orí òkè, ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wá pàdé rẹ̀.
38. Sì kíyèsí i, ọkùnrin kan nínú ìjọ kígbe sókè, pé “Olùkọ́ mo bẹ̀ ọ́, wo ọmọ mi: nítorí ọmọ mi kan ṣoṣo náà ni.