Lúùkù 4:24-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

24. Ó sì wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, kò sí wòlíì tí a tẹ́wọ́ gbà ní ilẹ̀ baba rẹ̀.

25. Ṣùgbọ́n mo wí fún un yín nítòótọ́, opó pípọ̀ ni ó wà ní Ísírẹ́lì nígbà tí ọ̀run fi sé ní ọdún mẹ́ta òun oṣù mẹ́fà, nígbà tí ìyàn ńlá fi mú ká ilẹ̀ gbogbo;

26. Kò sì sí ẹnìkan nínú wọn tí a rán Èlíjà sí, bí kò ṣe sí obìnrin opó kan ní Sáréfátì, ìlú kan ní Ṣídónì.

Lúùkù 4