Lúùkù 24:41-45 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

41. Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí?”

42. Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.

43. Ó sì gbà á, ó jẹ ẹ́ lójú wọn.

44. Ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni ọ̀rọ̀ tí mo sọ fún yín, nígbà tí èmí ti wà pẹ̀lú yín pé: A ní láti mú ohun gbogbo ṣẹ, tí a ti kọ nínú òfin Mósè, àti nínú ìwé àwọn wòlíì, àti nínú Sáàmù, nípasẹ̀ mi.”

45. Nígbà náà ni ó ṣí wọn níyè, kí ìwé mímọ́ lè yé wọn.

Lúùkù 24