Lúùkù 24:38-42 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

38. Ó sì wí fún wọn pé, “Èéṣe tí ara yín kò lélẹ̀? Èé sì ti ṣe tí ìròkúrò fi ń sọ nínú ọkàn yín?

39. Ẹ wo ọwọ́ mi àti ẹsẹ̀ mi, pé èmi tìkarami ni! Ẹ dì mí mú kí ẹ wò ó nítorí tí iwin kò ní ẹran àti egungun lára, bí ẹ̀yin ti rí tí èmi ní.”

40. Nígbà tí ó sì wí bẹ́ẹ̀ tan, ó fi ọwọ́ àti ẹsẹ̀ rẹ̀ hàn wọ́n.

41. Nígbà tí wọn kò sì tí ì gbàgbọ́ fún ayọ̀, àti fún ìyanu, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ní ohunkóhun jíjẹ níhín yìí?”

42. Wọ́n sì fún un ní ẹja tí a fi oyin sè.

Lúùkù 24