Lúùkù 15:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Tàbí obìnrin wo ni ó ní fàdákà mẹ́wàá bí ó bá sọ ọ̀kan nù, tí kì yóò tan fìtílà, kí ó fi gbá ilé, kí ó sì wá a gidigidi títí yóò fi rí i?

9. Nígbà tí ó sì rí i, ó pe àwọn ọ̀rẹ́ àti àwọn aládùúgbò rẹ̀ jọ, ó wí pé, ‘Ẹ bá mi yọ̀; nítorí mo rí fàdákà tí mo ti sọnù.’

10. Mo wí fún yín, gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni ayọ̀ ń bẹ níwájú àwọn ańgẹ́lì Ọlọ́run lórí ẹlẹ́sẹ̀ kan tí ó ronúpìwàdà.”

11. Ó sì wí pé ọkùnrin kan ní ọmọ méjì:

Lúùkù 15