9. Bí ó bá sì so èso, gẹ́gẹ́: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”
10. Ó sì ń kọ́ni nínú Sínágọ́gù kan ní ọjọ́ ìsinmi.
11. Sì kíyèsí i, obìnrin kan wà níbẹ̀ tí ó ní ẹmí àìlera, láti ọdún méjìdínlógún wá, ẹni tí ó tẹ̀ tán, tí kò le gbé ara rẹ̀ sókè bí ó ti wù kí ó ṣe.
12. Nígbà tí Jésù rí i, ó pè é sí ọ̀dọ̀, ó sì wí fún un pé, “Obìnrin yìí, a tú ọ sílẹ̀ lọ́wọ́ àìlera rẹ.”