Lúùkù 12:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

18. Ó sì wí pé, “Èyí ni èmi ó ṣe: èmi ó wó àká mi palẹ̀, èmi ó sì kọ́ èyí tí ó tóbi; níbẹ̀ ni èmi ó gbé to gbogbo èṣo àti ọrọ̀ mi jọ sí.

19. Èmi ó sì wí fún ọkàn mi pé, ọkàn, ìwọ ní ọrọ̀ púpọ̀ tí a tò jọ fún ọ̀pọ̀ ọdún; sinmi, máa jẹ, máa mu, má a yọ̀.”

20. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run wí fún un pé, “Ìwọ aṣiwèrè, lóru yìí ni a ó bèèrè ọkàn rẹ lọ́wọ́ rẹ; ǹjẹ́ ti tani nǹkan wọ̀nyí yóò ha ṣe, tí ìwọ ti pèsè sílẹ̀?”

21. “Bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó to ìsúra jọ fún ara rẹ̀, tí kò sì ní ọrọ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.”

Lúùkù 12