27. “ ‘Bí ènìyàn nínú àwọn ará ìlú bá ṣèèṣì ṣẹ̀ láìmọ̀ tí ó sì se ohun tí kò yẹ sí ọkan nínú àwọn òfin Olúwa, ó jẹ̀bi.
28. Nígbà tí a bá sọ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ fún un, ó gbọdọ̀ mú abo ewúrẹ́ tí kò ní àbùkù wá gẹ́gẹ́ bí ẹbọ fún ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.
29. Kí ó gbé ọwọ́ rẹ̀ lórí ewúrẹ́ ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ náà, kí ó sì pa á níbi ẹbọ sísun.