8. Àwọn márùn-ún péré nínú yín yóò máa sẹ́gun ọgọ́rùn-ún ènìyàn: Àwọn ọgọ́rùn-ún yóò sì máa sẹ́gun ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá: Àwọn ọ̀ta yín yóò tipa idà kú níwájú yín.
9. “ ‘Èmi yóò fi ojú rere wò yín: Èmi yóò mú kí ẹ bí sí i, èmi yóò jẹ́ kí ẹ pọ̀ sí i: Èmi yóò sì pa májẹ̀mú mi mọ́ pẹ̀lú yín.
10. Àwọn èrè oko yín yóò pọ̀ tóbẹ́ẹ̀ tí ẹ̀yin ó máa jẹ èrè ọdún tí ó kọjá, ẹ̀yin ó sì kó wọn jáde: kí ẹ̀yin lè rí àyè kó túntún sí.
11. Èmi yóò kọ́ àgọ́ mímọ́ mi sí àárin yín. Èmi kò sì ní kórìíra yín.
12. Èmi yóò wà pẹ̀lú yín: Èmi yóò máa jẹ́ Ọlọ́run yín: Ẹ̀yin yóò sì máa jẹ́ ènìyàn mi.
13. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde kúrò ní ilẹ̀ Éjíbítì: kí ẹ̀yin má baà jẹ́ ẹrú fún wọn mọ́. Mo sì já ìdè yín: mo sì mú kí ẹ̀yin máa rìn gẹ́gẹ́ bí ẹni tí a gbé lórí sókè.
14. “ ‘Bí ẹ̀yin kò bá fetí sí mi tí ẹ̀yin kò sì ṣe gbogbo òfin wọ̀nyí.