24. Ní gbogbo orílẹ̀ èdè ìní yín, ẹ fi àyè sílẹ̀ fún ìràpadà ilẹ̀ náà.
25. “ ‘Bí ọ̀kan nínú àwọn ènìyàn yín bá talákà, débi pé ó ta ara àwọn ẹrù rẹ̀, kí ará ilé rẹ̀ tí ó sún mọ́ ọ ra ohun tí ó tà padà.
26. Ẹni tí kò ní ẹni tó lè ràápadà fún un, tí òun fúnrarẹ̀ sì ti lọ́rọ̀, tí ó sì ní ànító láti rà á.
27. Kí ó mọ iye owó tí ó jẹ fún iye ọdún tí ó tà á, kí ó dá iye tí ó kù padà fún ẹni tí ó tà á fún: lẹ́yìn náà, ó lè padà sí ilẹ̀ ìní rẹ̀.
28. Ṣùgbọ́n bí kò bá rí ọ̀nà àti san án padà fún un. Ohun tí ó tà wà ní ìkáwọ́ ẹni tí ó ràá títí di ọdún ìdásílẹ̀. Kí ó dáa padà fún ẹni tí ó ni i ní ọdún ìdásílẹ̀, ẹni tí ó ni í tẹ́lẹ̀ lè tún padà gbà ohun ìní rẹ̀.
29. “ ‘Bí arákùnrin kan bá ta ilẹ̀ tí ó wà nínú ìlú, ó ní ẹ̀tọ́ láti rà á padà láàrin ọdún kan sí àkókò tí ó tà á.
30. Ṣùgbọ́n bí kò bá rà á padà láàrin ọdún náà ilé náà tí ó wà láàrin ìlú ni kí ó yọ̀ǹda pátapáta fún ẹni tí ó rà á, àti àwọn ìdílé rẹ̀. Kí wọ́n má da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.
31. Ṣùgbọ́n àwọn ilé tí ó wà ní abúlé láìní odi ni kí a kà gẹ́gẹ́ bí ilẹ̀ oko, a lè rà wọ́n padà, kí wọ́n sì da padà ní ọdún ìdásílẹ̀.
32. “ ‘Àwọn ọmọ Léfì ní ẹ̀tọ́, nígbàkugbà láti ra ilẹ̀ wọn, tí ó jẹ́ ohun ìní wọn ní àwọn ìlú tí ó jẹ́ ti ọmọ Léfì.
33. Torí náà ohun ìní àwọn ọmọ Léfì ni wọ́n rà padà, fún àpẹẹrẹ, èyí ni pé ilẹ̀ tí a bá tà ní ìlúkílú tí ó jẹ́ tiwọn, ó sì gbọdọ̀ di dídápadà ní ọdún ìdásílẹ̀, torí pé àwọn ilẹ̀ tí ó wà ní ìlú àwọn Léfì ni ìní wọn láàrin àwọn ará Ísírẹ́lì
34. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ tí wọ́n ti ń da ẹran tí ó jẹ́ ti ìlú wọn, wọn kò gbọdọ̀ tà wọ́n, ilẹ̀ ìní wọn láéláé ni.
35. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá talákà tí kò sì le è pèsè fún àìní ara rẹ̀: ẹ pèsè fún un bí ẹ ti ń ṣe fún àwọn àlejò tàbí àwọn tí ẹ gbà sílé: kí ó baà leè máa gbé láàrin yín.
36. Ẹ kò gbọdọ̀ gba èlé kankan lọ́wọ́ rẹ̀: ẹ bẹ̀rù Olúwa kí arákùnrin yín leè máa gbé láàrin yín.
37. Ẹ má ṣe gba èlé lórí owó tí ẹ yá a bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọdọ̀ jẹ èrè lórí oúnjẹ tí ẹ tà fún un.
38. Èmi ni Olúwa Ọlọ́run yín tí ó mú yín jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì láti fún yín ní ilẹ̀ Kénánì àti láti jẹ́ Ọlọ́run yín.
39. “ ‘Bí arákùnrin yín kan bá talákà débi pé ó ta ara rẹ̀ fún ọ bí ẹrú. Má se lò ó bí ẹrú.
40. Jẹ́ kí ó wà lọ́dọ̀ rẹ bí alágbàṣe tàbí àlejò láàrin yín: kí ó máa ṣiṣẹ́ sìn ọ́ títí di ọdún ìdásílẹ̀.
41. Nígbà náà ni kí ó yọ̀ǹda òun àti àwọn ọmọ rẹ̀, kí wọ́n padà sí ìdílé wọn àti sí ilẹ̀ ìní bàbá wọn.
42. Torí pé ìránṣẹ́ mi ni àwọn ará Ísírẹ́lì jẹ́. Ẹni tí mo mú jáde láti ilẹ̀ Éjíbítì wá, torí èyí ẹ kò gbọdọ̀ tà wọ́n lẹ́rú.