4. “ ‘Àwọn wọ̀nyí ni àwọn ọdún tí Olúwa yàn, ìpàdé àjọ mímọ́ tí ẹ gbọdọ̀ kéde lákókò wọn.
5. Àjọ ìrékọjá Olúwa bẹ̀rẹ̀ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹrìnlá oṣù kìn-ín-ní (Épírì).
6. Ní ọjọ́ kẹẹ̀dógún oṣù kìnm-ín-ní ni àjọ̀dún àkàrà àìwú (àkàrà tí kò ní ìwúkàrà) tí Olúwa bẹ̀rẹ̀ fún ọjọ́ méje ni ẹ gbọdọ̀ fi jẹ àkàrà tí kò ní ìwúkàrà.
7. Ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́ ní ọjọ́ kìn-ín-ní, ẹ kò sì gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́ yín.
8. Ọjọ́ méje ni kí ẹ fi mú ọrẹ tí a fi iná ṣe wá fún Olúwa. Ní ọjọ́ keje, ẹ pe ìpàdé àjọ mímọ́, ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ ojúmọ́.’ ”
9. Olúwa sọ fún Mósè pe
10. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì, kí o sì wí fún wọn pé, ‘Nígbà tí ẹ bá dé ilẹ̀ tí èmi yóò fún yín, tí ẹ bá ń ṣe ìkórè, kí ẹ mú síírì ọkà àkọ́kọ́ tí ẹ kórè wá fún àlùfáà.
11. Kí o fí síírì ọkà náà níwájú Olúwa, kí ó le jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà fún yín: kí àlùfáà fì í ní ọjọ́ kejì ìsinmi.