Léfítíkù 23:31-35 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

31. Ẹ kò gbọdọ̀ ṣe iṣẹ́ kankan rárá. Èyí yóò jẹ́ ìlànà ayérayé fún àwọn ìran tí ń bọ̀, níbikíbi tí ẹ bá ń gbé.

32. Ọjọ́ ìsinmi ni fún yín, ẹ gbọdọ̀ ṣẹ́ ara yín, láti ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kẹsàn-án oṣù náà, títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ tí ó tẹ̀ lé e, ni kí ẹ fi sinmi.”

33. Olúwa sọ fún Mósè pé,

34. “Sọ fún àwọn ará Ísírẹ́lì pé: ‘Ní ọjọ́ kẹẹdógún oṣù keje ni kí àjọ̀dún ọdún Àgọ́ ti Olúwa bẹ̀rẹ̀ kí ó sì wà títí di ọjọ́ méje.

35. Ọjọ́ kìn-ín-ní jẹ́ ọjọ́ ìpàdé mímọ́: ṣẹ kò gbọdọ̀ e iṣẹ́ ojúmọ́.

Léfítíkù 23