Léfítíkù 2:4-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

4. “ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ, èyí tí a yan lórí ààrò iná, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun kíkúná dáradára, àkàrà tí a se láì ní ìwúkàrà, tí a sì fi òróró pò àti àkàrà fẹ́lẹ́fẹ́lẹ́ tí a ṣe láì ní ìwúkàrà èyí tí a fi òróró pò.

5. Bí ó bá jẹ́ inú àwo pẹẹrẹ ni o ti se ohun jíjẹ rẹ, kí ó jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára tí a fi òróró pò, kò sì gbọdọ̀ ní ìwúkàrà.

6. Rún un kí o sì da òróró síi lórí, ọrẹ ohun jíjẹ ni.

Léfítíkù 2