Léfítíkù 19:16-19 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

16. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ máa ṣèyíṣọ̀hún bí olófofó láàrin àwọn ènìyàn rẹ.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ ṣe ohunkóhun tí yóò fi ẹ̀mi aládúgbò rẹ wéwu: Èmi ni Olúwa.

17. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ kóríra arákùnrin rẹ lọ́kàn rẹ, bá aládúgbò rẹ wí, kí o má baà jẹ́ alábápín nínú ẹ̀bi rẹ̀.

18. “ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbẹ̀san: má sì ṣe bínú sí èyíkéyí nínú àwọn ènìyàn rẹ. Ṣùgbọ́n, fẹ́ràn aládúgbò rẹ bí ara rẹ, Èmi ni Olúwa.

19. “ ‘Má a pa àṣẹ mi mọ́.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ jẹ́ kí ohun ọ̀sìn rẹ máa gùn pẹ̀lú ẹ̀yà mìíràn.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ gbin dàrúdàpọ̀ oríṣìí irúgbìn méjì sínú oko kan.“ ‘Ìwọ kò gbọdọ̀ wọ aṣọ èyí tí a fi oríṣìí ohun èlò ìhunṣọ méjì ṣe.

Léfítíkù 19