Léfítíkù 17:8-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

8. “Kí ó sọ fún wọn pé: ‘Ọkùnrin yówù kí ó jẹ́ ní ìdílé Ísírẹ́lì tàbí ti àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn tí ó bá rú ọrẹ sísun tàbí ṣe ẹbọ

9. tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí Olúwa irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni a ó gé kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

10. “ ‘Bí ẹnikẹ́ni bá jẹ ẹ̀jẹ̀ yálà nínú ìdílé Ísírẹ́lì tàbí àwọn àlejò tí ń gbé láàrin wọn: Èmi yóò bínú sí irú ẹni náà tí ó jẹ ẹ̀jẹ̀: èmi yóò sì gé e kúrò láàrin àwọn ènìyàn rẹ̀.

11. Nítorí pé nínú ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí ẹ̀dá wà èmi sì ti fi fún yín lórí pẹpẹ fún ètùtù ọkàn yín: nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ni a fi ń ṣe ètùtù fún ẹ̀mí ènìyàn.

Léfítíkù 17