Léfítíkù 15:2-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

2. Ẹ bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀: kí ẹ wí fún wọn pé: Bí ìṣunjáde bá ń jáde lára ọkùnrin kan lójú ara: ìṣunjáde náà jẹ́ àìmọ́.

3. Yálà ó ń jáde léraléra tàbí ó dúró, èyí yóò sọ ọ́ di aláìmọ́. Báyìí ni ìṣunjáde rẹ̀ ṣe le è sọ ọ́ di aláìmọ́.

4. “ ‘Gbogbo ibùsùn tí irú ẹni tí ó ní ìṣunjáde náà bá sùn di àìmọ́.

5. Bí ẹnikẹ́ni bá fi ara kan ibùsùn rẹ̀, ó gbọdọ̀ fọ aṣọ rẹ̀ kí ó sì wẹ̀. Yóò sì wà ní ipò àìmọ́ títí ìrọ̀lẹ́.

Léfítíkù 15