Léfítíkù 11:5-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé gára (ẹranko tí ó dàbí ehoro tí ń gbé inú àpáta) ń jẹ apojẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

6. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ehoro ń jẹ àpọ̀jẹ, ṣùgbọ́n kò ya pátakò ẹsẹ̀: àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

7. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹdẹ́ ya pátakò ẹṣẹ̀ ṣùgbọ́n kì í jẹ àpọ̀jẹ àìmọ́ lèyí jẹ́ fún yín.

8. Ẹ má ṣe jẹ ẹran wọn, ẹ kò sì gbọdọ̀ fọwọ́ kan òkú wọn. Àìmọ́ ni wọ́n jẹ́ fún yín.

Léfítíkù 11