10. Ẹ gbọdọ̀ mọ ìyàtọ̀ láàrin mímọ́ àti àìmọ́, láàrin èérí àti àìléérí.
11. Ẹ gbọdọ̀ kọ́ àwọn ara Ísírẹ́lì ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún wọn láti ẹnu Mósè.”
12. Mósè sì sọ fún Árónì, Élíásárì àti Ítamárì àwọn ọmọ rẹ̀ yóòkù pé “Ẹ mú ẹbọ ohun jíjẹ tó sẹ́kù láti inú ẹbọ àfinásun sí Olúwa, kí ẹ jẹ ẹ́ láì ní ìwúkàrà nínú, lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ nítorí ó jẹ́ mímọ́ jùlọ.