Kólósè 3:6-11 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

6. Lórí àwọn wọ̀nyìí ni ìbínú Ọlọ́run ńbọ̀ wá.

7. Ẹ máa ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀ nígbà tí ìgbé ayé yín sì jẹ́ apákan ayé yìí.

8. Ṣùgbọ́n báyìí, ẹ gbọdọ̀ fi àwọn wọ̀nyìí sílẹ̀: ìbínú, ìrúnú, àránkan, fífi ọ̀rọ̀-kẹ́lẹ́-ba-tẹni-jẹ́ àti ọ̀rọ̀ èérí kúrò ní ètè yín.

9. Ẹ má ṣe purọ́ fún ara yín, níwọ̀n ìgbà tí ẹ ti bọ́ ògbólógbòó ayé yín pẹ̀lú ìṣe rẹ̀ sílẹ̀,

10. tí ẹ sì ti gbé ìgbé ayé titun wọ̀, èyí tí a sọ di titun nínú ìmọ̀ ní ìbámu pẹ̀lú àwòrán ẹni tí ó dáa.

11. Níbi tí kò gbé sí Gíríkì tàbí Júù, ìkọlà tàbí aláìkọlà, aláìnímọ̀, ara Skitia, ẹrú tàbí òmìnira, ṣùgbọ́n Kírísítì ni ohun gbogbo nínú ohun gbogbo.

Kólósè 3