24. Wọ́n sì dá Jóṣúà lóhùn pé, “Nítorí tí a sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ dájú ṣáká bí Olúwa Ọlọ́run rẹ ti pàṣẹ fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ̀, láti fún yín ní gbogbo ilẹ̀ náà, kí ó sì pa gbogbo olùgbé ilẹ̀ náà run kúrò ní iwájú yín. Nítorí náà, àwa bẹ̀rù ẹ̀mí wa nítorí yín, èyí sì ni ìdí tí a fi ṣe bẹ́ẹ̀.
25. Nísinsinyí, àwa wà ní ọwọ́ yín. Ohunkóhun tí ẹ bá rò pé ó yẹ ó si tọ́ lójú yín ní kí ẹ fi wá ṣe.”
26. Bẹ́ẹ̀ ní Jóṣúà sì gbà wọ́n là kúrò ní ọwọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Wọn kò sì pa wọ́n.
27. Ní ọjọ́ náà ni ó sọ àwọn Gíbíónì di aṣẹ́gi àti apọnmi fún àwọn ará ìlú àti fún pẹpẹ Olúwa ní ibi tí Olúwa yóò yàn. Báyìí ní wọ́n wà títí di òní yìí.