Jóṣúà 7:15-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

15. Ẹnikẹ́ni tí a bá ká mọ́ pẹ̀lú ohun ìyàṣọ́tọ̀ náà, a ó fi iná paárun, pẹ̀lú gbogbo ohun tí ó ní. Ó ti ba májẹ̀mú Olúwa jẹ́, ó sì ti ṣe nǹkan ìtìjú ní Ísírẹ́lì!’ ”

16. Ní kùtùkùtù òwúrọ̀ ọjọ́ kéjì, Jóṣúà mú Ísírẹ́lì wá ṣíwájú ní ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan, a sì mú ẹ̀yà Júdà.

17. Àwọn agbo ilé e Júdà wá sí iwájú, ó sì mú agbo ilé Sérátì. Ó sì mú agbo ilé Sérátì wá ṣíwájú ní ìdílé kọ̀ọ̀kan, a sì mú ìdílé Símírì.

Jóṣúà 7