15. Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ìlérí dáradára gbogbo ti Olúwa Ọlọ́run yín ti wá sí ìmúsẹ, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa yóò mú ibi gbogbo tí ó ti kìlọ̀ wá sí orí yín, títí yóò fi pa yín run kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín.
16. Bí ẹ bá sẹ̀ sí májẹ̀mu Olúwa Ọlọ́run yín, èyí tí ó pàṣẹ fún un yín, tí ẹ bá sì lọ tí ẹ sì sin àwọn òrìṣà tí ẹ sì tẹ orí ba fún wọn, ìbínú gbígbóná Olúwa yóò wá sórí i yín, ẹ̀yin yóò sì ṣègbé kíákíá kúrò ní ilẹ̀ dáradára tí ó ti fi fún un yín”