Jóṣúà 21:37-43 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

37. Kédémótì àti Mẹ́fátì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ mẹ́rin.

38. Láti ara ẹ̀yà Gádì ní wọ́n ti fún wọn níRámótìa ní Gílíádì (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Máhánáímù,

39. Hésíbónì àti Jásérì, e pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn jẹ́ ìlú mẹ́rin.”

40. Gbogbo ìlú tí wọ́n pín fún àwọn ọmọ Mérárì tí wọ́n jẹ́ ìyókù àwọn ọmọ Léfì jẹ́ méjìlá.

41. Gbogbo ìlú àwọn ọmọ Léfì tó wà láàárin ara ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ méjìdínláádọ́ta lápapọ̀ pẹ̀lú pápá oko wọn.

42. Ọ̀kọ̀ọ̀kan ìlú wọ̀nyí ni ó ni ilẹ̀ pápá oko tí ó yí ì ká, bẹ́ẹ̀ náà ló rí fún gbogbo ìlú wọ̀nyí.

43. Báyìí ni Olúwa fún Ísírẹ́lì ní gbogbo ilẹ̀ tí ó ṣèlérí láti fi àwọn fún baba ńlá wọn. Nígbà tí wọ́n sì gbà á tan wọ́n sì tẹ̀dó síbẹ̀.

Jóṣúà 21