Jóṣúà 21:34-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

34. Láti ara ẹ̀yà Sébúlónì ni a ti fún ìdílé Mérárì (tí í ṣe ìyókù ọmọ Léfì) ní:“Jókíníámù, Kárítà,

35. Dímínà àti Náhálálì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ ìlú mẹ́rin.

36. Láti ara ẹ̀yà Rúbẹ́nì ni wọ́n ti fún wọn níBésérì, àti Jáhásì,

37. Kédémótì àti Mẹ́fátì, pẹ̀lú ilẹ̀ pápá oko wọn, wọ́n jẹ́ mẹ́rin.

38. Láti ara ẹ̀yà Gádì ní wọ́n ti fún wọn níRámótìa ní Gílíádì (tí ó jẹ́ ìlú ààbò fún apànìyàn), Máhánáímù,

Jóṣúà 21