Jóṣúà 17:17-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

17. Ṣùgbọ́n Jóṣúà sọ fún àwọn ilé Jósẹ́fù: fún Éfúráímù àti Mánásè pé, “Lóòtọ́ ni ẹ pọ̀ lọ́pọ̀lọpọ̀, ẹ sì jẹ́ alágbára. Ẹ̀yin kí yóò sì ní ìpín kan ṣoṣo.

18. Ṣùgbọ́n ilẹ̀ orí òkè igbo jẹ́ tiyín pẹ̀lú. Ẹ ṣán ilẹ̀ náà, òpin rẹ̀ yóò jẹ́ tiyín pátapáta. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ará Kénánì ní kẹ̀kẹ́ ogun irin, tí ó sì jẹ́ pé wọ́n ní agbára, ṣíbẹ̀ ẹ lè lé wọn jáde.”

Jóṣúà 17