Jóṣúà 17:13-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde Òní (BMY)

13. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará Ísírẹ́lì di alágbára, wọ́n mú àwọn ọmọ Kénánì sìn, ṣùgbọ́n wọn kò lé wọn jáde pátapáta.

14. Àwọn ẹ̀yà Jósẹ́fù méjèèje sì sọ fún Jóṣúà pé, “Kí ló dé ìwọ fi fún wa ní ìpín ilẹ̀ kan àti ìdá kan ní ìní? Nítorí àwa jẹ́ ọ̀pọ̀ ènìyàn tí Olúwa ti bùkún lọ́pọ̀lọpọ̀.”

15. Jóṣúà dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ bá pọ̀ bẹ́ẹ̀, tí òkè ìlú Éfúráímù bá kéré fún yin, ẹ gòkè lọ sí igbó kí ẹ sì sán ilẹ̀ òkè fún ara yín ní ibẹ̀ ní ilẹ̀ àwọn ará Pérísì àti ará Réfì.”

Jóṣúà 17